Postproverbials in Yoruba (Nigeria)

Curator(s)

Prof. Aderemi Raji-Oyelade

remraj1@gmail.com

University of Ibadan, Ibadan, Nigeria.

Postproverbial: Eni tó gbódó mì, kò le è r’íìdí jókòó.
Translation: [For] he who swallows a mortar or pestle, there is no respite of sitting.
Proverb: Ẹni tó gbódó mì, ìdúró kò sí, ìbere kò sí.
Translation: [For] he who swallows a mortar or pestle, there is no rest, neither standing nor stooping.
Language - Region: Yoruba (Nigeria)
Read more
Postproverbial: Eni tó gbódó mì, kò ní jẹ́ ká r’íyán jẹ.
Translation: He who swallows a mortar or pestle, causes us to lose the chance of eating pounded yam.
Proverb: Ẹni tó gbódó mì, ìdúró kò sí, ìbere kò sí.
Translation: [For] he who swallows a mortar or pestle, there is no rest, neither standing nor stooping.
Language - Region: Yoruba (Nigeria)
Read more
Postproverbial: Eni tó gbódó mì, kò lè di ọjọ́ kejì.
Translation: He who swallows a mortar or pestle, will not survive the second day.
Proverb: Ẹni tó gbódó mì, ìdúró kò sí, ìbere kò sí.
Translation: [For] he who swallows a mortar or pestle, there is no rest, neither standing nor stooping.
Language - Region: Yoruba (Nigeria)
Read more
Postproverbial: Ẹni tó gbépo lájà fẹ́ sebẹ̀ ni.
Translation: He who steals the palm oil from the rafters (certainly) desires to cook.
Proverb: Ẹni tó gbépo lájà kò jalè bí eni tí ó gbà á síle.
Translation: He who steals the palm oil from the rafters is no less a thief than his accomplice.
Language - Region: Yoruba (Nigeria)
Read more
Postproverbial: Ẹni tó gbépo lájà, olè paraku ni.
Translation: He who steals the palm oil from the rafters is a certified thief.
Proverb: Ẹni tó gbépo lájà kò jalè bí eni tí ó gbà á síle.
Translation: He who steals the palm oil from the rafters is no less a thief than his accomplice.
Language - Region: Yoruba (Nigeria)
Read more
Postproverbial: Ẹni tó bá forí tì í títí dé òpin, àfàìmọ̀ ni kò fi ní di aláàárù.
Translation: He who endures (carrying with his head) till the end may, if care is not taken, become a porter of sorts.
Proverb: Ẹni tó bá forí tì í títí dé òpin, ni à ó gbàlà.
Translation: He who endures (carrying with his head) till the end, shall be saved.
Language - Region: Yoruba (Nigeria)
Read more
Postproverbial: Ẹni tó fò sókè, ó fẹ́ kí gbogbo ènìyàn rí òun ni.
Translation: He who jumps up, desires to be seen by all.
Proverb: Ẹni tó fò sókè, ó bẹ́ ijó lórí.
Translation: He who jumps up, has opened the rhythm of dance.
Language - Region: Yoruba (Nigeria)
Read more
Postproverbial: Ẹni tí yóò j'oyin inú àpáta, yóò mú'ra kóle.
Translation: He who savours the honey in the rock will brace up for hard work.
Proverb: Ẹni tí yóò j'oyin inú àpáta, kìí w’enu àáké.
Translation: He who savours the honey in the rock will not mind what happens to the blade of his axe.
Language - Region: Yoruba (Nigeria)
Read more
Postproverbial: Ẹni tí kò mọ ibi t’ẹ́gbẹ́ ẹ̀ ti là, á sáré, á sáré s’ẹ́nu mọ́tò ni
Translation: He who does not know how his mate gets wealthy will run and run, until he runs into a car.
Proverb: Ẹni tí kò mọ ibi t’ẹ́gbẹ́ ẹ̀ ti là, yóò wulẹ̀ sáré kú.
Translation: He who does not know how his mate gets wealthy, will keep running until he dies.
Language - Region: Yoruba (Nigeria)
Read more
Postproverbial: Ẹni tí ẹ̀gún bá gún l’ẹ́sẹ̀, fún ra rẹ̀ ni yóò yọ ọ́.
Translation: He who has thorns in his foot, will remove it by himself.
Proverb: Ẹni tí ẹ̀gún bá gún l’ẹ́sẹ̀, níí ṣe lákáńlàká tọ alábẹ.
Translation: He who has thorns in his foot, will limp in need to the physician.
Language - Region: Yoruba (Nigeria)
Read more