Postproverbials in Yoruba (Nigeria)

Curator(s)

Prof. Aderemi Raji-Oyelade

remraj1@gmail.com

University of Ibadan, Ibadan, Nigeria.

Postproverbial: Ọwọ́ ọmọdé kò tó pẹpẹ, kò gun orí àpótí ni.
Translation: The hand of the child does not reach the rafter, only if he has not climbed the stool.
Proverb: Ọwọ́ ọmọdé kò tó pẹpẹ, t’àgbàlagbà kò wọ akèrègbè.
Translation: The hand of the child does not reach the rafter, that of the elder does not enter the gourd.
Language - Region: Yoruba (Nigeria)
Read more
Postproverbial: Owó ni ẹ̀rẹ̀kẹ́ ìyìn rere.
Translation: Money is the cheek of the good gospel
Proverb: Owó ni kẹ̀kẹ́ ìyìn rere.
Translation: Money is the wheel of the good gospel.
Language - Region: Yoruba (Nigeria)
Read more
Postproverbial: Ọwọ́ la fi ń’mẹ́ran láwo.
Translation: With the hands (touch), we pick the good meat in the stew.
Proverb: Orí la fi ń’mẹ́ran láwo.
Translation: With the head (luck), we pick the good meat in the stew.
Language - Region: Yoruba (Nigeria)
Read more
Postproverbial: Ojú la fi ń’mẹ́ran láwo.
Translation: With the eyes (senses), we pick the good meat in the stew.
Proverb: Orí la fi ń’mẹ́ran láwo.
Translation: With the head (luck), we pick the good meat in the stew.
Language - Region: Yoruba (Nigeria)
Read more
Postproverbial: Onísàngó tó jó tí kò tà’pá, kò gbọ́ ìlù òní bàtá ni.
Translation: The Sango worshipper who dances without kicking the feet, must be deaf to the bata drummer’s beats.
Proverb: Onísàngó tó jó tí kò tà’pá, àbùkù ara rẹ̀ ló tà.
Translation: The Sango worshipper who dances without kicking the feet has diminished himself.
Language - Region: Yoruba (Nigeria)
Read more
Postproverbial: Ohun tó ń’ṣe Abọ́yadé, kò ṣe Onífádé mọ́.
Translation: The affliction of Aboyade, chief priest of Oya, is no more a problem to other worshippers, not the least Onifade, the Ifa priest.
Proverb: Ohun tó ń’ṣe Abọ́yadé, gbogbo ọlọ́ya ní ń’ṣe.
Translation: The affliction of Aboyade, chief priest of Oya, is also the general problem of other worshippers.
Language - Region: Yoruba (Nigeria)
Read more
Postproverbial: Ojú ló mọ ohun tó l’óyún.
Translation: The eye-gauge will tell which person or thing is pregnant.
Proverb: Ojú ló mọ ohun tó yó’nú.
Translation: The eye-gauge will tell which meal will be satisfying.
Language - Region: Yoruba (Nigeria)
Read more
Postproverbial: Ọ̀gẹ̀dẹ̀ dúdú kò yá bù sán, pupa ló se é dín dòdò.
Translation: (As) the unripe plantain is not fit for consumption, only the ripe one is good for frying.
Proverb: Ọ̀gẹ̀dẹ̀ dúdú kò yá bù sán, Ọmọ burúkú kò yá lù pa.
Translation: (As) the unripe plantain is not fit for consumption, (so) it is not easy to beat the irresponsible child to death.
Language - Region: Yoruba (Nigeria)
Read more
Postproverbial: Ọbẹ̀ tó dùn, owó Ọlọ́pàá!
Translation: The delicious stew, the policeman’s wealth!
Proverb: Ọbẹ̀ tó dùn, owó ló pa á.
Translation: The delicious stew, is made possible by cash.
Language - Region: Yoruba (Nigeria)
Read more
Postproverbial: Ọbẹ̀ tó dùn, mummy ló sè é
Translation: The delicious stew, is prepared by mother.
Proverb: Ọbẹ̀ tó dùn, owó ló pa á.
Translation: The delicious stew, is made possible by cash.
Language - Region: Yoruba (Nigeria)
Read more