Postproverbials in Yoruba (Nigeria)

Curator(s)

Prof. Aderemi Raji-Oyelade

remraj1@gmail.com

University of Ibadan, Ibadan, Nigeria.

Postproverbial: Agbójú l’ógún, ó fẹ́ jẹ ń’bẹ̀ ni.
Translation: He who depends on the inheritance, surely wants a share of the property.
Proverb: Agbójú l’ógún, fi ara rẹ̀ f’ósì ta.
Translation: He who depends on the inheritance, leaves himself as pawn to poverty.
Language - Region: Yoruba (Nigeria)
Read more
Postproverbial: Àgbàtán làá gbọ̀lẹ; bí a fún un lóúnjẹ, à á f’ọbẹ̀ síi.
Translation: A lazy man should be helped completely; when you give him food, you must also provide the stew.
Proverb: Àgbàtán làá gbọ̀lẹ; bí a d’áṣọ fún un, à á pa á láro
Translation: A lazy man should be helped completely; when you buy him a cloth, you must also dye it.
Language - Region: Yoruba (Nigeria)
Read more
Postproverbial: Àgbàtán làá gbọ̀lẹ; bí a bá là ní jà, à á mú u délé.
Translation: The lazy man must be fully supported; when you stop him in a fight, you must escort him to his home.
Proverb: Àgbàtán làá gbọ̀lẹ; bí a d’áṣọ fún un, à á pa á láro
Translation: A lazy man should be helped completely; when you buy him a cloth, you must also dye it.
Language - Region: Yoruba (Nigeria)
Read more
Postproverbial: Afọwọ́fọn’ná, á f’ọwọ́ jó’ná.
Translation: The barehand stoker will have his palms scorched
Proverb: Afọwọ́fọn’ná, kìí dúró ro’jọ́.
Translation: The barehand stoker does not wait to banter.
Language - Region: Yoruba (Nigeria)
Read more
Postproverbial: Afẹ́nilóbìnrin, ẹnu rẹ̀ ló dùn.
Translation: The wife-snatcher is surely sweet-mouthed.
Proverb: Afẹ́nilóbìnrin, kò kọ àtipani.
Translation: The wife-snatcher does not mind killing the husband.
Language - Region: Yoruba (Nigeria)
Read more
Postproverbial: Afẹ́niláya kò jẹ̀bi; aya yín ni ẹ kìlọ̀ fún.
Translation: The wife-snatcher is not at fault; it is your wife that should be admonished.
Proverb: Afẹ́niláya kìí f’ojú ire woni.
Translation: The wife-snatcher will not be courteous to the husband.
Language - Region: Yoruba (Nigeria)
Read more
Postproverbial: Afẹ́fẹ́ ti fẹ́, a ti rí ohun tó ń dún nínú rádíò.
Translation: The wind has blown, we have seen the transistor secrets of the radio.
Proverb: Afẹ́fẹ́ ti fẹ́, a ti rí fùrọ̀ Adìyẹ.
Translation: The wind has blown, we have seen the anus of the fowl.
Language - Region: Yoruba (Nigeria)
Read more
Postproverbial: Adìyẹ funfun, ló dára lọ́dẹ̀dẹ̀.
Translation: The white hen is suitable in the homestead.
Proverb: Adìyẹ funfun, kò mọ ara rẹ̀ l’ágbà.
Translation: The white hen does not know itself as the elder.
Language - Region: Yoruba (Nigeria)
Read more