Proverbs

Proverb: Ọbẹ̀ tí baálé ilé kìí jẹ, ìyálé ilé kìí sè é.
Translation: The stew that is forbidden to the husband, the senior wife does not cook it.
Language - Region: yoruba-nigeria
Proverb: Ọbẹ̀ kìí mì ní ikùn àgbà.
Translation: The soup does not shake in the belly of the elder.
Language - Region: yoruba-nigeria
Proverb: Mọ̀‘jà mọ̀’sá là á mọ akínkanjú; akínkanjú tó mọ̀’jà tí ò mọ̀’sá, irú wọn níí b’ógun lọ.
Translation: Attack and retreat is the stuff of a great warrior; the warrior who knows how to fight but doesn’t know when to retreat will die with the war.
Language - Region: yoruba-nigeria
Proverb: Màlúù tí kò ní’rù, Olúwa níí bá a léṣinṣin.
Translation: As for the cow that has no tail, God is its repellant against flies.
Language - Region: yoruba-nigeria
Proverb: Kò sí ẹni tí kìí rẹ̀.
Translation: There is no one who is never exhausted.
Language - Region: yoruba-nigeria
Proverb: K’ójú má ríbi, ẹsẹ̀ loògùn un rẹ̀.
Translation: That the eyes may not witness calamity, the leg is its solution.
Language - Region: yoruba-nigeria
Proverb: Ìyàwó ọlẹ là á gbà, kò sẹ́ni tó lè gba ọmọ ọlẹ.
Translation: It is only the wife of the lazy man that can be taken, no one can claim the child of the lazy man.
Language - Region: yoruba-nigeria
Proverb: Ìwà l’ẹwà lọ́dọ̀ t’èmi.
Translation: Character is beauty to me.
Language - Region: yoruba-nigeria
Proverb: Ìrà á pé, ìranù ni kò suwọ̀n.
Translation: Vanity may pay, vagabondage is not proper
Language - Region: yoruba-nigeria
Proverb: Ilé Ọba tó jó, ẹwà ló bù kún un.
Translation: The palace that is burnt will make a more magnificent edifice.
Language - Region: yoruba-nigeria