Proverbs

Proverb: Ayé l’ọjà, ọ̀run n’ilé.
Translation: The world is a marketplace; heaven is the home.
Language - Region: yoruba-nigeria
Proverb: Àpọ́nlé ni Ìyá Káà, kò sẹ́ni tó wà ní Káà tí ò lórúkọ.
Translation: It’s a sheer honour to be called “Court Matriarch”, there’s no woman who does not have a proper name.
Language - Region: yoruba-nigeria
Proverb: À kúkú ù joyè, ó sàn ju “enu mi ò ká ìlú”.
Translation: Better not to be made a chief, than to say “I am incapable of controlling my people”.
Language - Region: yoruba-nigeria
Proverb: A kìí gba àkàkà lọ́wọ́ akítì, a kìí gba’lée baba ẹni lọ́wọ́ ẹni.
Translation: No one stops a monkey from somersaulting; no one can claim a child’s father’s house from him.
Language - Region: yoruba-nigeria
Proverb: A kì í f’ọmọ ọrẹ̀ b’ọrẹ̀.
Translation: No one sacrifices the child of an idol to the same idol.
Language - Region: yoruba-nigeria
Proverb: A kì í f’árí apákan ká d’ápá kan sí.
Translation: It is taboo to shave one part of the head and leave a portion uncut.
Language - Region: yoruba-nigeria
Proverb: Àjọjẹ kò dùn, b’ẹ́nì kan kò ní.
Translation: Sharing the meal cannot be enjoyable, when one in the group has not.
Language - Region: yoruba-nigeria
Proverb: À jẹ ìwèyìn, ló ba ẹlẹ́dẹ̀ jẹ́.
Translation: Selfishness – eating without hindsight is the flaw of the pig.
Language - Region: yoruba-nigeria
Proverb: Àìtètè m’ólè, olè ń m’ólóko.
Translation: In the hesitation to catch the thief, the thief arrests the farmer.
Language - Region: yoruba-nigeria
Proverb: Àìtètè l’óbìnrin kò pé ká má bí ọmọ, àrẹ̀mọ wọn níí kéré.
Translation: A prolonged bachelorhood does not prevent child-bearing, only the first born will come too late and young.
Language - Region: yoruba-nigeria