Proverbs

Proverb: Àìsí nílé ológbò, ilé d’ilé èkúté.
Translation: The cat is not in the house, the home becomes the playground of rats.
Language - Region: yoruba-nigeria
Proverb: Àìlówó lọ́wọ́ kò pa ni l’órúkọ dà.
Translation: Being poor does not change one’s name.
Language - Region: yoruba-nigeria
Proverb: Àìgbọ́fá là’ń w’òkè, Ifá kan ò sí ní párá.
Translation: Not knowing Ifa philosophy, we gaze up, but the Oracle is not in the rafters.
Language - Region: yoruba-nigeria
Proverb: Agbójú l’ógún, fi ara rẹ̀ f’ósì ta.
Translation: He who depends on the inheritance, leaves himself as pawn to poverty.
Language - Region: yoruba-nigeria
Proverb: Àgbàtán làá gbọ̀lẹ; bí a d’áṣọ fún un, à á pa á láro
Translation: A lazy man should be helped completely; when you buy him a cloth, you must also dye it.
Language - Region: yoruba-nigeria
Proverb: Afọwọ́fọn’ná, kìí dúró ro’jọ́.
Translation: The barehand stoker does not wait to banter.
Language - Region: yoruba-nigeria
Proverb: Afẹ́nilóbìnrin, kò kọ àtipani.
Translation: The wife-snatcher does not mind killing the husband.
Language - Region: yoruba-nigeria
Proverb: Afẹ́niláya kìí f’ojú ire woni.
Translation: The wife-snatcher will not be courteous to the husband.
Language - Region: yoruba-nigeria
Proverb: Afẹ́fẹ́ ti fẹ́, a ti rí fùrọ̀ Adìyẹ.
Translation: The wind has blown, we have seen the anus of the fowl.
Language - Region: yoruba-nigeria
Proverb: Adìyẹ funfun, kò mọ ara rẹ̀ l’ágbà.
Translation: The white hen does not know itself as the elder.
Language - Region: yoruba-nigeria